-
2 Sámúẹ́lì 17:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà náà, Áhítófẹ́lì sọ fún Ábúsálómù pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yan ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ọkùnrin, kí a sì gbéra láti lépa Dáfídì lálẹ́ òní. 2 Màá yọ sí i nígbà tó bá ti rẹ̀ ẹ́, tí kò sì ní agbára kankan,*+ màá mú kí ẹ̀rù bà á; gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ á sá lọ, màá sì pa ọba nìkan.+ 3 Màá wá kó gbogbo àwọn èèyàn náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ò ń lépa yìí ló máa sọ bóyá àwọn èèyàn náà máa pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Ìgbà náà ni gbogbo àwọn èèyàn náà yóò wà ní àlàáfíà.”
-