25 Ábúsálómù fi Ámásà+ sí ipò Jóábù+ láti máa darí àwọn ọmọ ogun; Ámásà jẹ́ ọmọ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ítírà, ọmọ Ísírẹ́lì ni Ítírà, òun ló ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Ábígẹ́lì+ ọmọ Náháṣì, arábìnrin Seruáyà, ìyá Jóábù.
16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruáyà àti Ábígẹ́lì.+ Àwọn ọmọ Seruáyà ni Ábíṣáì,+ Jóábù+ àti Ásáhélì,+ àwọn mẹ́ta. 17 Ábígẹ́lì bí Ámásà,+ bàbá Ámásà sì ni Jétà ọmọ Íṣímáẹ́lì.