-
2 Sámúẹ́lì 9:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ìránṣẹ́ ilé Sọ́ọ̀lù kan wà tó ń jẹ́ Síbà.+ Torí náà, wọ́n pè é wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ ni Síbà?” Ó dáhùn pé: “Èmi ìránṣẹ́ rẹ ni.”
-
-
2 Sámúẹ́lì 16:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tí Dáfídì kọjá orí òkè+ náà díẹ̀, Síbà+ ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́,* igba (200) búrẹ́dì, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù àjàrà gbígbẹ, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn* àti ìṣà* wáìnì ńlá+ kan sì wà lórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
-