21 Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti agbègbè olókè Éfúrémù,+ ti dìtẹ̀ sí Ọba Dáfídì. Tí ẹ bá lè fi ọkùnrin yìí nìkan lé mi lọ́wọ́, màá fi ìlú yìí sílẹ̀.” Obìnrin náà bá sọ fún Jóábù pé: “Wò ó! A ó ju orí rẹ̀ sí ọ láti orí ògiri!”