-
Oníwàásù 9:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà. 15 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+
-