-
2 Sámúẹ́lì 4:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Jónátánì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ní ọmọkùnrin kan tó rọ lẹ́sẹ̀.*+ Ọmọ ọdún márùn-ún ni nígbà tí wọ́n mú ìròyìn wá láti Jésírẹ́lì+ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú, ẹni tó ń tọ́jú rẹ̀ bá gbé e, ó sì sá lọ, àmọ́ bí ẹ̀rù ṣe ń ba obìnrin náà nígbà tó ń sá lọ, ọmọ náà já bọ́, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì rọ. Orúkọ rẹ̀ ni Méfíbóṣétì.+
-
-
2 Sámúẹ́lì 19:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Méfíbóṣétì,+ ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù, náà wá pàdé ọba. Kò tíì wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò gé irun imú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti lọ títí di ọjọ́ tó pa dà ní àlàáfíà.
-