20Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Dánì+ títí lọ dé Bíá-ṣébà àti ilẹ̀ Gílíádì,+ gbogbo àpéjọ náà sì kóra jọ sójú kan* níwájú Jèhófà ní Mísípà.+
2 Nítorí náà, ọba sọ fún Jóábù+ olórí àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, lọ yí ká gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà,+ kí ẹ sì forúkọ àwọn èèyàn náà sílẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.”