6 Ìdààmú bá Dáfídì gan-an, torí àwọn ọkùnrin náà ń sọ pé àwọn máa sọ ọ́ lókùúta, torí inú bí gbogbo àwọn ọkùnrin náà gan-an, nítorí àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn tí wọ́n kó lọ. Àmọ́ Dáfídì fún ara rẹ̀ lókun látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+
12 Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, agbani-nímọ̀ràn*+ Dáfídì, láti Gílò+ ìlú rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ náà ń gbilẹ̀ sí i, àwọn tó sì wà lẹ́yìn Ábúsálómù ń pọ̀ sí i.+