29 Tí ẹnì kan bá dìde láti lépa rẹ, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi ẹ̀mí* olúwa mi pa mọ́ sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti ẹ̀mí* àwọn ọ̀tá rẹ, òun yóò ta á jáde bí ìgbà tí èèyàn fi kànnàkànnà ta òkúta.*
19 Áhímáásì+ ọmọ Sádókù sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti bá a dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ bí ó ṣe gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+