28Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+
5 Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fi í lé ọwọ́ ọba Síríà,+ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rú, wọ́n kó wọn wá sí Damásíkù.+ Ọlọ́run tún fi í lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì, ẹni tó pa òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ lọ rẹpẹtẹ.