46 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Mú ìkóná, kí o fi iná sí i látorí pẹpẹ,+ kí o fi tùràrí sí i, kí o wá yára lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ torí pé Jèhófà ti bínú sí wọn gan-an. Àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀!”
24 Jóábù ọmọ Seruáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn èèyàn, àmọ́ kò kà wọ́n parí; Ọlọ́run bínú sí Ísírẹ́lì* nítorí nǹkan yìí,+ a kò sì kọ iye náà sínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbà Ọba Dáfídì.