-
Jóṣúà 17:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ní ilẹ̀ Ísákà àti Áṣérì, wọ́n fún Mánásè ní Bẹti-ṣéánì àti àwọn àrọko rẹ̀,* Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Ẹ́ń-dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn tó ń gbé Mẹ́gídò àti àwọn àrọko rẹ̀, mẹ́ta nínú àwọn ibi tó ga.
-
-
1 Sámúẹ́lì 31:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára àwọn tí wọ́n pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti kú sórí Òkè Gíbóà.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 31:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Wọ́n wá gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé àwọn ère Áṣítórétì, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ògiri Bẹti-ṣánì.+
-