-
Àwọn Onídàájọ́ 9:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Wọ́n wá fún un ní àádọ́rin (70) ẹyọ fàdákà látinú ilé* Baali-bérítì,+ Ábímélékì sì fi gba àwọn ọkùnrin tí kò níṣẹ́ tí wọ́n sì ya aláfojúdi, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé e kiri. 5 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà,+ ó sì pa àwọn arákùnrin rẹ̀,+ àwọn ọmọ Jerubáálì, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan. Jótámù, ọmọ Jerubáálì tó kéré jù nìkan ló ṣẹ́ kù, torí pé ó sá pa mọ́.
6 Gbogbo àwọn olórí Ṣékémù àti gbogbo Bẹti-mílò wá kóra jọ, wọ́n sì fi Ábímélékì jọba,+ nítòsí igi ńlá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* tó wà ní Ṣékémù.
-
-
1 Àwọn Ọba 1:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ojú ọ̀dàlẹ̀ ni wọ́n máa fi wo èmi àti Sólómọ́nì ọmọ mi ní gbàrà tí olúwa mi ọba bá ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.”
-