5 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà pẹ̀lú onírúurú ohun ìkọrin tí a fi igi júnípà ṣe pẹ̀lú háàpù àti àwọn ohun ìkọrin míì tó ní okùn tín-ín-rín+ àti ìlù tanboríìnì+ àti sítírọ́mù pẹ̀lú síńbálì.*+
15 Ó fi àwọn pátákó kédárì bo* àwọn ògiri inú ilé náà. Ó fi àwọn ẹ̀là gẹdú bo ògiri inú, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé tó wà ní àjà, ó sì fi àwọn pátákó júnípà+ bo ilẹ̀ ilé náà.