-
1 Àwọn Ọba 1:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Wọlé lọ bá Ọba Dáfídì, kí o sọ fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ṣebí ìwọ lo búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: “Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi”?+ Kí ló dé tí Ádóníjà fi wá di ọba?’
-
-
1 Kíróníkà 22:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+ 10 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.+ Á di ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ Màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.’+
-