3 “Ní ọdún kìíní Ọba Kírúsì, Ọba Kírúsì pa àṣẹ kan nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, ó ní:+ ‘Ẹ tún ilé náà kọ́ kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ níbẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ sí àyè rẹ̀; kí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,+