6 Ní báyìí, sọ fún àwọn èèyàn rẹ pé kí wọ́n gé igi kédárì ti Lẹ́bánónì+ fún mi. Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́, màá san owó iṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, iye tí o bá sì sọ ni màá san, nítorí o mọ̀ pé kò sí ìkankan lára wa tó mọ bí a ṣe ń gé igi bí àwọn ọmọ Sídónì.”+