24 Ẹnu ọ̀nà náà ní ilẹ̀kùn méjì tó ṣeé ṣí síbí sọ́hùn-ún, ilẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan sì ní awẹ́ méjì. 25 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ sára àwọn ilẹ̀kùn ibi mímọ́, bíi ti èyí tó wà lára àwọn ògiri.+ Ìbòrí kan tí wọ́n fi pákó ṣe wà níwájú ibi àbáwọlé níta.