16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+
25 Torí náà, ìyàn ńlá+ kan mú ní Samáríà, wọ́n sì dó tì í títí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ kan ní ọgọ́rin (80) ẹyọ fàdákà, ìlàrin òṣùwọ̀n káàbù* imí àdàbà sì di ẹyọ fàdákà márùn-ún.