-
2 Kíróníkà 7:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 “Ní tìrẹ, tí o bá rìn níwájú mi bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn, tí ò ń ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń pa àwọn ìlànà mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́,+ 18 ìgbà náà ni màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀,+ bí mo ṣe bá Dáfídì bàbá rẹ dá májẹ̀mú pé,+ ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ tí yóò máa ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì.’+
-