-
2 Kíróníkà 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ọbabìnrin Ṣébà+ gbọ́ ìròyìn Sólómọ́nì, torí náà ó wá sí Jerúsálẹ́mù, kó lè fi àwọn ìbéèrè tó ta kókó* dán an wò. Àwọn abọ́barìn* tó gbayì ló tẹ̀ lé e pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù àti wúrà tó pọ̀ gan-an+ àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+ 2 Sólómọ́nì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ohun tó ṣòro* fún Sólómọ́nì láti ṣàlàyé fún un.
-