28 Nítorí náà, gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, ohun tí ọba ṣe yìí sì jọ wọ́n lójú gidigidi,*+ torí wọ́n rí i pé ó ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.+
9 Kì í ṣe pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n nìkan ni, ó tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó mọ̀,+ ó ronú jinlẹ̀, ó sì wádìí fínnífínní, kí ó lè kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ.*+