ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 9:3-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 4 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà,+ ẹnu yà á gan-an.* 5 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 6 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i.+ Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tí o ní kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá.+ O ti ré kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́ nípa rẹ.+ 7 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ! 8 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Torí pé Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì,+ ó fi ọ́ jọba lé e lórí láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo, kó lè mú kí Ísírẹ́lì máa wà títí lọ.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́