-
2 Kíróníkà 9:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ọba tún fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì fi ògidì wúrà bò ó.+ 18 Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, àpótí ìtìsẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe tún wà lára ìtẹ́ náà, ibi ìgbápálé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà, ère kìnnìún+ kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. 19 Àwọn kìnnìún+ tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan. Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí.
-