30 Èmi yóò run àwọn ibi gíga+ tí ẹ ti ń sin àwọn òrìṣà yín, màá wó àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀, màá sì to òkú yín jọ pelemọ sórí òkú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ yín, èmi* yóò pa yín tì, màá sì kórìíra yín.+
52 Kí ẹ lé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, kí ẹ run gbogbo ère tí wọ́n fi òkúta+ ṣe àti gbogbo ère onírin*+ wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga+ tí wọ́n ti ń jọ́sìn àwọn òrìṣà.
3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ pa run,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe òpó òrìṣà,*+ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe.+ Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+