13 Ọba sọ àwọn ibi gíga tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, èyí tó wà ní gúúsù Òkè Ìparun, tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì mọ fún Áṣítórétì abo ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Sídónì; fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra Móábù àti fún Mílíkómù+ ọlọ́run ẹ̀gbin àwọn ọmọ Ámónì.+