-
2 Kíróníkà 10:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Lẹ́yìn náà, Ọba Rèhóbóámù rán Hádórámù,+ ẹni tó jẹ́ olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Agbára káká ni Ọba Rèhóbóámù fi rọ́nà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.
-