-
2 Kíróníkà 9:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì,+ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Nátánì,+ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò àti nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìran Ídò+ aríran tó sọ nípa Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì? 30 Sólómọ́nì fi ogójì (40) ọdún jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì. 31 Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀;+ Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
-