26 Ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì nínú ẹ̀yà Éfúrémù, ó wá láti Sérédà, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì+ ni. Sérúà lorúkọ ìyá rẹ̀, opó sì ni. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀* sí ọba.+
40 Torí náà, Sólómọ́nì wá ọ̀nà láti pa Jèróbóámù, àmọ́ Jèróbóámù sá lọ sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì,+ ó sì ń gbé ní Íjíbítì títí Sólómọ́nì fi kú.