15 Ó tún wó pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ibi gíga tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì kọ́, tó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Lẹ́yìn tó wó pẹpẹ yẹn àti ibi gíga náà, ó dáná sun ibi gíga náà, ó lọ̀ ọ́ kúnná, ó sì sun òpó òrìṣà*+ náà.
19 Jòsáyà tún mú gbogbo àwọn ilé ìjọsìn tó wà lórí àwọn ibi gíga kúrò ní àwọn ìlú Samáríà,+ èyí tí àwọn ọba Ísírẹ́lì kọ́ láti mú Ọlọ́run bínú, ohun tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ló ṣe sí àwọn náà.+