64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+
29 Nígbà ayé Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà kógun wọ Íjónì, Ebẹli-bẹti-máákà,+ Jánóà, Kédéṣì,+ Hásórì, Gílíádì+ àti Gálílì, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì gbà á, ó wá kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+
11 Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì ní kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+