-
2 Kíróníkà 11:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Rèhóbóámù nífẹ̀ẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù ju gbogbo àwọn ìyàwó rẹ̀ yòókù àti àwọn wáhàrì*+ rẹ̀ lọ. Ó ní ìyàwó méjìdínlógún (18) àti ọgọ́ta (60) wáhàrì, ó sì bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti ọgọ́ta (60) ọmọbìnrin. 22 Nítorí náà, Rèhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Máákà ṣe olórí àti aṣáájú láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, torí ó fẹ́ fi jọba.
-