-
1 Àwọn Ọba 14:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ohun tí o ṣe burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ, o ṣe ọlọ́run míì fún ara rẹ àti àwọn ère onírin* láti mú mi bínú,+ o sì kẹ̀yìn sí mi.+ 10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan!
-