-
Àìsáyà 44:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Kò sí ẹni tó rò ó nínú ọkàn rẹ̀,
Tó ní ìmọ̀ tàbí òye, pé:
“Mo ti dáná sun ìdajì rẹ̀,
Ẹyin iná rẹ̀ ni mo fi yan búrẹ́dì, tí mo sì fi yan ẹran tí màá jẹ.
Ṣé ó wá yẹ kí n fi èyí tó kù ṣe ohun ìríra?+
Ṣé ó yẹ kí n máa sin ìtì igi* tí mo gé lára igi?”
20 Ó ń jẹ eérú.
Ọkàn rẹ̀ tí wọ́n ti tàn jẹ ti kó o ṣìnà.
Kò lè gba ara* rẹ̀, kì í sì í sọ pé:
“Ṣé irọ́ kọ́ ló wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí?”
-