3 Àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí fún Dáfídì ní Hébúrónì+ nìyí: Ámínónì+ àkọ́bí, ìyá rẹ̀ ni Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì; ìkejì ni Dáníẹ́lì, ìyá rẹ̀ ni Ábígẹ́lì+ ará Kámẹ́lì; 2 ìkẹta ni Ábúsálómù+ ọmọ Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Géṣúrì; ìkẹrin ni Ádóníjà+ ọmọ Hágítì;