ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 9:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Lẹ́yìn náà, Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì dìtẹ̀ sí Jèhórámù.

      Ní àkókò yẹn, Jèhórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì wà ní Ramoti-gílíádì,+ wọn ò sì dẹra nù nítorí Hásáẹ́lì+ ọba Síríà.

  • 2 Àwọn Ọba 9:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Jéhù mú ọfà,* ó sì ta á lu Jèhórámù ní àárín méjì ẹ̀yìn rẹ̀, ọfà náà jáde ní ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

  • 2 Àwọn Ọba 10:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ló bá kọ lẹ́tà kejì sí wọn, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé tèmi lẹ̀ ń ṣe, tó sì wù yín láti ṣègbọràn sí mi, ẹ kó orí àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì wá bá mi ní Jésírẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”

      Lákòókò yìí, àádọ́rin (70) àwọn ọmọkùnrin ọba wà lọ́dọ̀ àwọn sàràkí ọkùnrin ìlú, ìyẹn àwọn tó ń tọ́ wọn. 7 Gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n kó àwọn ọmọkùnrin ọba, wọ́n sì pa wọ́n, àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin,+ wọ́n kó orí wọn sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí i ní Jésírẹ́lì.

  • 2 Àwọn Ọba 10:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Lẹ́yìn náà, Jéhù àti Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù wọ inú ilé Báálì. Ó wá sọ fún àwọn tó ń jọ́sìn Báálì pé: “Ẹ fara balẹ̀ wá ibí yìí dáadáa pé kò sí olùjọsìn Jèhófà kankan níbí, àfi àwọn olùjọsìn Báálì nìkan.”

  • 2 Àwọn Ọba 10:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Gbàrà tí Jéhù rú ẹbọ sísun náà tán, ó sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́* àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun pé: “Ẹ wọlé, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn lọ!”+ Torí náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun fi idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n gbé òkú wọn jù síta, wọ́n sì ń lọ títí dé ibi mímọ́* ilé Báálì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́