3 Ìgbà náà ni àwọn ọmọ wòlíì* ní Bẹ́tẹ́lì jáde wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?”+ Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”
11 Ni Jèhóṣáfátì bá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí tó lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà ni?”+ Torí náà, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé: “Èlíṣà+ ọmọ Ṣáfátì, ẹni tó máa ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà*+ wà níbí.”