-
Ẹ́kísódù 6:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Màá mú yín bí èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín.+ Ó dájú pé ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín tó mú yín kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn ará Íjíbítì.
-
-
Ẹ́kísódù 7:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.”
-
-
Ìsíkíẹ́lì 6:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Èmi yóò na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ wọ́n, màá sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, ibi tí wọ́n ń gbé máa di ahoro ju aginjù tó wà nítòsí Díbílà lọ. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
-