-
2 Kíróníkà 18:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó lọ sọ́dọ̀ Áhábù ní Samáríà,+ Áhábù sì pa ọ̀pọ̀ àgùntàn àti màlúù* fún òun àti àwọn tó bá a wá. Ó wá rọ̀ ọ́* pé kó tẹ̀ lé òun lọ gbéjà ko Ramoti-gílíádì.+ 3 Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ṣé wàá tẹ̀ lé mi lọ sí Ramoti-gílíádì?” Ó dá a lóhùn pé: “Ìkan náà ni èmi àti ìwọ, ìkan náà sì ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ, a ó tì ọ́ lẹ́yìn nínú ogun náà.”
-