7 Ó tún ránṣẹ́ sí Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ọba Móábù ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé wàá tẹ̀ lé mi, ká lọ bá Móábù jà?” Ó dáhùn pé: “Màá tẹ̀ lé ọ.+ Ìkan náà ni èmi àti ìwọ. Ìkan náà ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Ìkan náà sì ni àwọn ẹṣin mi àti àwọn ẹṣin rẹ.”+
2 Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ aríran jáde lọ bá Ọba Jèhóṣáfátì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé èèyàn burúkú ló yẹ kí o máa ràn lọ́wọ́,+ ṣé àwọn tó kórìíra Jèhófà ló sì yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?+ Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ.