22 Ni Dáfídì bá sọ fún Ábíátárì pé: “Mo mọ̀ lọ́jọ́ yẹn,+ tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wà níbẹ̀, pé kò ní ṣaláì sọ fún Sọ́ọ̀lù. Tìtorí mi ni wọ́n ṣe pa gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ. 23 Dúró sọ́dọ̀ mi. Má bẹ̀rù, torí ẹni tí ó bá ń wá ẹ̀mí rẹ ń wá ẹ̀mí mi; abẹ́ ààbò mi lo wà.”+