-
2 Àwọn Ọba 7:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nígbà náà, Èlíṣà sọ pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n síà* ìyẹ̀fun kíkúnná yóò di ṣékélì* kan, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì yóò sì di ṣékélì kan ní ẹnubodè* Samáríà.’”+ 2 Ni olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tí ọba fọkàn tán bá dá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn pé: “Ká tiẹ̀ ní Jèhófà ṣí ibú omi ojú ọ̀run sílẹ̀, ṣé irú nǹkan* yìí lè ṣẹlẹ̀?”+ Èlíṣà dáhùn pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i,+ ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.”+
-