12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún un pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Jésírẹ́lì,* torí pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, màá pe ilé Jéhù+ wá jíhìn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó wáyé ní Jésírẹ́lì, màá sì fòpin sí ìṣàkóso ilé Ísírẹ́lì.+