-
2 Kíróníkà 23:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta lára àwọn àlùfáà àti lára àwọn ọmọ Léfì tó máa wà lẹ́nu iṣẹ́+ ní Sábáàtì máa jẹ́ aṣọ́nà;+ 5 ìdá mẹ́ta míì máa wà ní ilé* ọba,+ ìdá mẹ́ta tó kù á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn náà á sì wà ní àwọn àgbàlá ilé Jèhófà.+ 6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ ilé Jèhófà àfi àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣe ìránṣẹ́.+ Àwọn yìí lè wọlé torí pé àwùjọ mímọ́ ni wọ́n, gbogbo àwọn èèyàn náà yóò sì máa ṣe ojúṣe wọn fún Jèhófà. 7 Àwọn ọmọ Léfì gbọ́dọ̀ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá wọlé. Kí ẹ sì dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*
-