14 Gbàrà tí wọ́n ṣe tán, wọ́n kó owó tó ṣẹ́ kù wá fún ọba àti Jèhóádà, wọ́n sì fi ṣe àwọn nǹkan èlò fún ilé Jèhófà, àwọn nǹkan èlò fún iṣẹ́ ìsìn àti fún rírú ẹbọ àti àwọn ife àti àwọn nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà.+ Wọ́n máa ń rú àwọn ẹbọ sísun+ déédéé ní ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jèhóádà.