-
2 Kíróníkà 28:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ní ti ìyókù ìtàn rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.+ 27 Níkẹyìn, Áhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ìlú náà, ní Jerúsálẹ́mù, nítorí wọn kò gbé e wá sí ibi tí wọ́n sin àwọn ọba Ísírẹ́lì sí.+ Hẹsikáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
-