-
2 Àwọn Ọba 17:3-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Hóṣéà,+ Hóṣéà sì di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í san ìṣákọ́lẹ̀* fún Ṣálímánésà.+ 4 Àmọ́, ọba Ásíríà rí i pé Hóṣéà ti ń lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀, nítorí ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Sóò ọba Íjíbítì,+ kò sì mú ìṣákọ́lẹ̀* wá fún ọba Ásíríà bíi ti àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá. Nítorí náà, ọba Ásíríà tì í mọ́ inú ẹ̀wọ̀n, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é.
5 Ọba Ásíríà ya wọ gbogbo ilẹ̀ náà, ó wá sí Samáríà, ọdún mẹ́ta ló sì fi dó tì í. 6 Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà.+ Ó wá kó àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+
-