-
1 Kíróníkà 29:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nígbà náà, Dáfídì yin Jèhófà lójú gbogbo ìjọ náà. Dáfídì sọ pé: “Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, títí láé àti láéláé.* 11 Jèhófà, tìrẹ ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá,*+ nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.+ Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba.+ Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo.
-