-
Léfítíkù 25:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àmọ́ kí ọdún keje jẹ́ sábáàtì fún ilẹ̀ náà, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ kankan níbẹ̀, sábáàtì fún Jèhófà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí oko yín tàbí kí ẹ rẹ́wọ́ àjàrà yín. 5 Ẹ ò gbọ́dọ̀ kórè ohun tó hù fúnra rẹ̀ látinú ọkà tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí ẹ kórè, ẹ má sì kó àwọn èso àjàrà yín tí ẹ ò tíì rẹ́wọ́ rẹ̀ jọ. Ẹ jẹ́ kí ilẹ̀ náà sinmi pátápátá fún ọdún kan. 6 Àmọ́ ẹ lè jẹ ohun tó bá hù ní ilẹ̀ náà nígbà sábáàtì rẹ̀; ẹ̀yin, ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àwọn alágbàṣe yín àti àwọn àjèjì tó ń gbé láàárín yín lè jẹ ẹ́,
-