-
2 Kíróníkà 34:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ṣáfánì mú ìwé náà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún wọn. 17 Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ti kó o fún àwọn ọkùnrin tí a yàn àti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà.” 18 Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.”+ Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.+
-